a Isa 15–16; 25.10-12; Jr 48; El 25.8-11; Sf 2.8-11.

Amos 2

1 aÈyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí ó ti sun ún, di eérú,
egungun ọba Edomu
2Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè
3Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
4Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀
wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́
Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà
òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé
5Èmi yóò rán iná sí orí Juda
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

Ìdájọ́ tí yóò wá sórí Israẹli

6Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Wọ́n ta olódodo fún fàdákà
àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
7Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀
bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára
Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà
Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́
8Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ
Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.

9“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn
gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.
Òun sì le koko bí igi óákù
mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá
àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
10Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.

11“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
ni Olúwa wí.
12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu
e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.

13“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀
bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.
14Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ
alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀
jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
15Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin
kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
16Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ
yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,”
ni Olúwa wí.
Copyright information for YorBMYO